Ń gbé fídíò wá
Àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀
Yoruba (Èdè Yorùbá)
Bọ́ọ̀lù jẹ́ ohun kan tí a fi awọ, rọ́bà tí a rán ṣe.
Kìí ṣe ohun kan tí ó jẹ́ bàbàrà.
Ogúnlọ́gọ̀ wọn ni ó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè l'ágbàyéé.
Ṣùgbọ́n nígbàtí ó bá wà lórí pápá...
kò sí ohun kankan tí ó ṣe pàtàkì jùú lọ.
Gbogbo agbá bọ́ọ̀lù lórí pápá
ni ó máa ńfẹ́ mọ̀ ibití ó wà ní pàtó.
Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibi ìjókòó pápá-ìṣeré a máa lọọgun pẹ̀lú ìdùnú.
Wọn a gbàgbé gbogbo ayé wọn,
gbogbo rẹ̀ nítorí bọ́ọ̀lù yìí.
Nígbàtí a gbá bọ́ọ̀lù kan bá gba bọ́ọ̀lù,
aá gba gbogbo àtẹjúmọ́ àti ìfọkànsí wọn.
Fún wọn, ní àkókò yìí,
kò sí ohun mìíràn àti ẹlòmíràn mọ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ.
Wọn kìí bìkítà iye agbára tí yóò gbà wọn,
tàbí bí wọn yóò ṣe jẹ ìrora tó nígbàtí ó bá ṣe.
Pàápàá, wọ́n a ti ẹ tún fi ara wọn dáàbòbò bọ́ọ̀lù náà.
Ohun kankṣoṣo ní ó yẹ láti ṣe...
rírí wípé bọ́ọ̀lù náà dé ibití ó yẹ kí ó wà.
Ohun kan tí ó lè yà ọ́ lẹ́nu ni wípé...
Báyẹn ni Jésù ṣe ńrí ọ.
Jésù mọ ohun gbogbo nípa rẹ.
Tí Òun sì ńgbà ọ́ bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí,
tí ó sì ńfẹ́ láti dáàbòbò ọ́ kí ó sì ṣe àbójútó rẹ.
Jésù pàápàá tí ẹ̀ fi ayé Rẹ̀ sílẹ̀ fún èrèdí kanṣoṣo,
èrèdí tí ó gba gbogbo àtẹjúmọ́ àti ìfọkànsí...
kí o ba a lè wà ní ibití o yẹ kí o wà...
Ilé.
Pẹ̀lú Rẹ̀.
Níbití ó yẹ kí o wà.
Lẹ́yìn tí ìdíje kan bá parí,
gbogbo ènìyàn yóò fi pápá-ìṣeré náà sílẹ̀.
Ṣùgbọ́n Jésù ṣì ńdúró.
Dè ọ́.
Jésù nífẹ̀ẹ́ rẹ.
Ìpinnu náà wà lọ́wọ́ rẹ láti ṣe.
Jẹ́ kí Òun mú ọ wá sílé.