JF Language Stack Collection·49 nínú 84

Àwòrán kékeré Tümlükden Nura
OríTümlükden Nura
Àwòrán kékeré Çoğu Çay (Mostly Tea)
OríÇoğu Çay (Mostly Tea)
Àwòrán kékeré Jätku Leiba
OríJätku Leiba
Àwòrán kékeré La Liberté De L’Interieur - Freedom Within
OríLa Liberté De L’Interieur - Freedom Within

Where You Belong

On the field, there is nothing more important than the ball. The players will do everything to protect it and get the ball where it belongs. In the Game of Life, where do you belong?

Béèrè tìrẹ

Àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì

Pín
Psalm 86:15

But You, O Lord, are a compassionate and gracious God, slow to anger, abounding in loving devotion and faithfulness.

Berean Standard Bible

Public Domain

Kà sí i...
Àwọn orísun ọ̀fẹ́

Ṣé o fẹ́ lóye Bíbélì jinlẹ̀ sí i?

Darapọ̀ mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa

Àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀

Yoruba (Èdè Yorùbá)
Bọ́ọ̀lù jẹ́ ohun kan tí a fi awọ, rọ́bà tí a rán ṣe. Kìí ṣe ohun kan tí ó jẹ́ bàbàrà. Ogúnlọ́gọ̀ wọn ni ó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè l'ágbàyéé. Ṣùgbọ́n nígbàtí ó bá wà lórí pápá... kò sí ohun kankan tí ó ṣe pàtàkì jùú lọ. Gbogbo agbá bọ́ọ̀lù lórí pápá ni ó máa ńfẹ́ mọ̀ ibití ó wà ní pàtó. Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibi ìjókòó pápá-ìṣeré a máa lọọgun pẹ̀lú ìdùnú. Wọn a gbàgbé gbogbo ayé wọn, gbogbo rẹ̀ nítorí bọ́ọ̀lù yìí. Nígbàtí a gbá bọ́ọ̀lù kan bá gba bọ́ọ̀lù, aá gba gbogbo àtẹjúmọ́ àti ìfọkànsí wọn. Fún wọn, ní àkókò yìí, kò sí ohun mìíràn àti ẹlòmíràn mọ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ. Wọn kìí bìkítà iye agbára tí yóò gbà wọn, tàbí bí wọn yóò ṣe jẹ ìrora tó nígbàtí ó bá ṣe. Pàápàá, wọ́n a ti ẹ tún fi ara wọn dáàbòbò bọ́ọ̀lù náà. Ohun kankṣoṣo ní ó yẹ láti ṣe... rírí wípé bọ́ọ̀lù náà dé ibití ó yẹ kí ó wà. Ohun kan tí ó lè yà ọ́ lẹ́nu ni wípé... Báyẹn ni Jésù ṣe ńrí ọ. Jésù mọ ohun gbogbo nípa rẹ. Tí Òun sì ńgbà ọ́ bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, tí ó sì ńfẹ́ láti dáàbòbò ọ́ kí ó sì ṣe àbójútó rẹ. Jésù pàápàá tí ẹ̀ fi ayé Rẹ̀ sílẹ̀ fún èrèdí kanṣoṣo, èrèdí tí ó gba gbogbo àtẹjúmọ́ àti ìfọkànsí... kí o ba a lè wà ní ibití o yẹ kí o wà... Ilé. Pẹ̀lú Rẹ̀. Níbití ó yẹ kí o wà. Lẹ́yìn tí ìdíje kan bá parí, gbogbo ènìyàn yóò fi pápá-ìṣeré náà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù ṣì ńdúró. Dè ọ́. Jésù nífẹ̀ẹ́ rẹ. Ìpinnu náà wà lọ́wọ́ rẹ láti ṣe. Jẹ́ kí Òun mú ọ wá sílé.
JesusFilm